POWER OF RESURRECTION DRAMA MINISTRY

IDARIJI

 

SCENE 1

Awon egbe eniyan kan ti won wo aso dudu n daro, won si n sokun tele oku ti a di pelu aso funfun leyin. Awon okunrin meji lo gbe oku naa. Ni ori itage, won te oku naa sori aga, awon eniyan naa n to tele ara won lati wo oju oku. Leyin eyi, Pastor so oro iyanju.

Pastor:              eyin ara ninu Oluwa, gbogbo igokegodo eniyan laye, ibi ti yoo pari re si niyi. Bi o ti wu ki a sare lati lowo tabi lati je eniyan to, gbogbo wa n bo ni ipo yii lojo kan. Sugbon, iku kii se adanu, eni ti ko ni Jesu, ti ko si di eni igbala ki o to ku ni o padanu, iru eni bee sofo emi. Ara, e ma sokun mo, bi o ti wu ki a sokun to, ko le ji oloogbe Olugbenga Oladapo dide.

 

Gajumo:           Pastor, e kan ni ki a ma sokun mo ni, se iru baba yii lo ye ki o ku? Nigba ti iya n je mi loju mejeeji, baba yii lo ba mi ya owo ti mo fi bere okowo mi, o fi ile ati moto re se iduro titi o fi ri owo naa san pada won o si gba kobo lowo mi. okowo yii ni o so mi di eniyan Pataki lawujo lonii. O mase o (o tun bu sekun)

 

Folasade:          iku ri eni ibi nile, ko mu won, alaanu mi ni o wa mu lo. Iranlowo baba ni mo fi di eni to n lo si ilu oyinbo bi eni to n lo si eko ni gbogbo igba. Baba yii ni o gba emi ati idile mi lowo osi ati iponju. Pastor, nigbakan, mo talaka ju ekute church lo, opelope baba yii lara mi. ah, iku doro (o n sokun, o si n nu oju re pelu aso pelebe {handkerchief})

 

Pastor:              ooto ni gbogbo ohun ti e so. Ise nla ni baba ti gbe se ninu ijo Olorun. Nigba aye won, won sin Oluwa pelu gbogbo okan ati ohun gbogbo ti won ni. Won maa n toju awon iranse Olorun, koda nipase won ni a fi ra ile ti a ko ile isin wa si. O damiloju pe won o gba ere won no kikun lodo Jesu.

 

Taiwo:              e wo o, oro temi yato si tiyin. Mo je okan lara awon to n sise ni ile ise ti baba ti koko sise. (o sokun bi o se n soro) emi ni mo fa a ti won fi da baba duro lenu ise naa ti won si gba gbogbo ohun ini won lori ese ti won o mowo ti won o mese (enu ya awon yooku). Emi ni mo yi iwe ti a fi gba opoplopo owo jade ninu apo ile ise sugbon oga ro pe baba mo nipa re nitori baba ati oga ni o lase lati fowo si iwe owo (enu ya awon eniyan,).

 

Iyawo:              Iwo ni o gba ise lowo oko mi, o so wa sinu iponju fun ogun odun, loni ni iwo naa yoo ku (o fo mo Taiwo, o si n lo aso mo lorun, awon eniyan ja a kuro lara re won si tu u)

 

Taiwo:              Leyin opolopo odun, ojiji ni gbogbo nkan daru fun mi, ko si si ona abayo, eyi lo mu mi di ero ile ijosin kan nibiti mo ti di eni igbala. Lojokan nigba ti awon iranse Olorun n gbadura fun mi ni emi Oluwa ti so fun mi pe kin lo jewo ese yii fun baba ki won le dariji mi ki won si sure fun mi, mo si gbe igbese naa sugbon inu bi baba, won le mi bi aja, won ko si sure fun mi titi won fi ku. Pastor, e gba mi, se o le dara fun mi laye mo bayii? (O bu sekun)

 

Pastor:              (O mi kanle) o mase o! niwon igba ti e ti yipada kuro ninu ona buburu yin atijo, e ti di eda titun, oku ko le gbadura fun yin, afi ki e maa wa oju rere ati aanu Olorun. Ju gbogbo re lo, eni ti o sin oku lose oku, awon to n sokun ariwo lasan ni won n pa. e je ki a lo te oloogbe si ibi isinmi. Ki Oluwa duro ti aya ati awon omo  ti won fi sile.

(Awon okunrin naa gbe oku, awon yooku n korin tele won leyin titi won fi jade)

 

SCENE 2

 

Ni orun, Gbenga ro aso funfun, o n lo sibi isinmi re sugbon o pade Arugbo-ojo, eni to wo aso funfun ti o si ni irun funfun lori re. Gbenga teriba fun un sugbon Arugbo-ojo mi ori fun-un.

 

Arugbo:            Olugbenga omo Oladapo, o ku irin. O se mi laanu pe o ko le ba mi pin ninu ijoba mi

 

Gbenga:            (o ta giri) Oluwa, kilo de? Iwo ni mo fi gbogbo ojo aye mi sin, mo n toju awon iriju re ninu aye, mo n ran awon alaini lowo gege bi ase re, gbogbo ofin ati ilana re ni mo pa mo ninu aye. Kilo de ti o fi wipe mi o ni ipin ninu ijoba re?

 

Arugbo:            Olugbenga omo Oladapo, gbogbo akitiyan re laye ni mo ri, o ni eri rere lodo eniyan, okankan ninu ise re ko lo lasan. Wo o (o na ika si ibikan) ere ise re niyen.

 

Gbenga:            ehn? Odidi adugbo? Ere ise mi? Oluwa, je kin maa lo sibe, kin lo maa gbadun ere ise ti mo se.

 

Arugbo:            o ko le lo, nitori o ko lati dariji iranse mi, Taiwo omo Adejare eni ti awon orun n yo pe o di eni igbala.

 

Gbenga:            Oluwa, Taiwo omo Adejare lo se okunfa iya ti mo je ni ogun odun ki ona to la fun mi. ohun to se fun mi dun mi gidigidi. Mi o le dariji i o.

 

Arugbo:            leyin iya ogun odun naa, ti emi Oluwa si la ona fun o, nje o ranti iya ati iponju naa mo? Se ogbon re ni o fi ri ona abayo si isoro re ni? Taiwo omo Adejare ti gba mi ni Oluwa ati Olugbala re mo si ti dari gbogbo ese re ji i. mo kan fe ki o mo pe mo wa pelu re ni mo se pase fun Taiwo ki o jewo ese naa fun o sugbon o ko lati dariji i. eyi ni o se idena fun o lati pelu mi ninu ijoba mi ti o si padanu ere re. Mo so ninu oro mi pe bi eyin ba fi ese awon eniyan ji won, baba yin ti nbe lorun yoo fi ese tiyin ji yi. Olugbenga omo Oladapo, o korira Taiwo eyi ti o lodi si ase mi, enikeni ti o ba korira arakunrin re, apaniyan ni ko si si apaniyan kan ti yoo ni iye ainipekun lati maa gbe ninu re.

 

Gbenga:            (o kunle, o bu sekun) Oluwa, saanu fun mi, je kin lo se atunse ki ma ba padanu awon ere ise mi

 

Arugbo:            (o mi ori) a ti fi lele fun eniyan lati ku leekan, leyin eyi, idajo.

 

Gbenga:            Oluwa saanu mi (o n sokun kikan)

 

Arugbo:            (oju re le) kuro lodo mi iwo onise ese (o yi eyin pada, o si lo. Gbenga n be e, sugbon ko da a lohun. Bi Gbenga se n sokun lowo, Esu wole, o n fi se eleya)

 

Esu:                  Olugbenga omo Oladapo, ko tan bi? Gbogbo ilakaka re ti ja si asan, elomiran ni yoo gba ere ise re (o rerin-in). Nigba ti o wa laye, mo ni ki o se temi, sugbon kaka ki o je omo eyin mi, nise ni o n ni mi lara ti o si da ijoba mi laamu pelu awon adura ina ti o maa n gba. Wa gbo o, asiko niyi fun mi lati gbesan ti ko si eni ti yoo gba o sile lowo mi, emi yoo maa da o loro losan ati loru titi lailai. (Gbenga n be e, Esu rerein-in, O n fiya je e, lai pe o gbe e jade).

 

 

SCENE 3

 

Gbenga jade lati inu yara re, o lo towel mo idi, o si n da soro

 

Gbenga:            iru ala buburu wo niyi? Sebi won ni bi omo Olorun ba ti n sunmo iku, yoo maa ri iran awon angeli ti won yo pelu Jesu nitori pe o fe lo sile isinmi, sugbon iran orun apaadi ni emi n ri. Oluwa saanu mi, maje kin pari irnajo mi sodo satani. To ba je nitori aidariji Taiwo ni yoo dena mi lodo re, Taiwo omo Adejare, mo dariji o lati inu okan mi, gbogbo ohun ti o ba n dawo le ni yoo maa yori si rere lati oni lo loruko Jesu. (o kunle pelu omije) Oluwa, dariji mi, mo ti dariji Taiwo, saanu mi, ma je kin padanu ijoba re ( o sokun jade)

 

 

 

THE END

 

 

 

CAST

 

PASTOR……………………………………………EVANG. ASIYANBI

GBAJUMO…………………………………………MRS. ADEBAYO

TAIWO……………………………………………..BRO. ADEBAYO      

FOLASADE………………………………………...SIS. GRACE

GBENGA……………………………………………BRO. OLAYINKA

ARUGBO-OJO…………………………………….BRO. OLUWOLE

ESU…………………………………………………BRO. OLUWASEYI

IYAWO…………………………………………….SIS. MOJI

OMO……………………………………………….SIS. OLUWATOYIN

AWON TO GBE OKU……………………………BRO. OLUWASEYI &

BRO. ANTHONY